THE PRAISES OF GOD / ORÍKÌ ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ


Ọba tó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù / The LORD reigns HE is clothed with majesty
Tó sì di agbára ni àmùrè / HE has girded HIMSELF with strength.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀ / The world is firmly established
Kò sì ní yẹ̀ laelae / It cannot be moved forever
ìdí ìjọba OLODUMARE múlẹ̀ láti ìgbà laelae / YOUR throne is established from of old
Láti ayérayé ni ỌLỌRUN ti wà / YOU are from everlasting.
Ibú omi gbé ohùn wọn sókè si OLUWA / The floods have lifted up their voices to the LORD
Ó sì ń sán bí ààrá / The sea roars
OLUWA lágbára lókè! / The LORD on high is mightier
ÓLUWA lágbára ju ariwo omi òkun lọ / The LORD on high is mightier
Than the noise of many waters,

ÓLUWA lágbára ju ìgbì omi òkun lọ / Than the mighty waves of…

View original post 220 more words


ỌLỌRUN ỌBA / GOD ALMIGHTY.



Ọba tó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù / The LORD reigns HE is clothed with majesty
Tó sì di agbára ni àmùrè / HE has girded HIMSELF with strength.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀ / The world is firmly established
Kò sì ní yẹ̀ laelae / It cannot be moved forever
ìdí ìjọba OLODUMARE múlẹ̀ láti ìgbà laelae / YOUR throne is established from of old
Láti ayérayé ni ỌLỌRUN ti wà / YOU are from everlasting.
Ibú omi gbé ohùn wọn sókè si OLUWA / The floods have lifted up their voices to the LORD
Ó sì ń sán bí ààrá / The sea roars
OLUWA lágbára lókè! / The LORD on high is mightier
ÓLUWA lágbára ju ariwo omi òkun lọ / The LORD on high is mightier
Than the noise of many waters,

ÓLUWA lágbára ju ìgbì omi òkun lọ / Than the mighty waves of the sea.
Àwọn òfin OLODUMARE kìí yipada / The testimonies of the ALMIGHTY are very sure
ìwà mímọ́ ni ilé ỌLỌRUN títí lae / Holiness adorns YOUR house, O LORD, forever.
ỌLỌRUN Onídàájọ́ Gbogbo Ayé / GOD, the Refuge of the Righteous
OLUWA, ỌLỌRUN ẹ̀san / The LORD GOD, to whom vengeance belongs
Ti i fi agbára hàn / HIS awesome mighty power is visible to all
onídàájọ́ ayé / Judge of all the earth
ỌLỌRUN tí ó dá etí, tí a fi n gbọ́ràn / HE planted the ear
Eni tí ó dá ojú tí a fi n ríran / HE formed the eye
Tí ń fún eniyan ní ìmọ̀ ati oye / HE teaches man knowledge
OLUWA ti o mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan /The LORD knows the thoughts of man
ỌLỌRUN OLODUMARE mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni / HE knows that they are futile
ìfẹ́ OLUWA kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró / YOUR mercy, O LORD, will hold me up.
Olutunu awon tí o ni àìbàlẹ̀ ọkàn / The comfort of the restless
OLUWA ni ibi ìsádi mi / the LORD has been my defense
ỌLỌRUN sì ni àpáta ààbò mi /And my GOD the rock of my refuge.

H A L L E L U J A H ! ! !


ỌLỌRUN OLùMọ̀RÀN ỌKÀN

OLUWA mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde;
OLUWA mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré.

2YOU know when I sit and when I rise YOU perceive my thoughts from afar.
OLUWA yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò;
gbogbo ọ̀nà mi ni OLODUMARE sì mọ̀.

3YOU discern my going out and my lying down; YOU are familiar with all my ways.
Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,
OLUWA, ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata.

Before a word is on my tongue YOU, LORD, know it completely.
OLUWA pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn;
OLUWA n gbé ọwọ́ ààbò lé mi.

YOU hem me in behind and before, and you lay YOUR hand upon me.
Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi, ó ga jù, ojú mi kò tó o.
Such knowledge is too wonderful for me, too lofty for me to attain.
Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí OLUWA kò ní sí níbẹ̀?
Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú OLORUN kò ní tó mi?

Where can I go from YOUR Spirit? Where can I flee from YOUR presence?
Ǹ báà gòkè re ọ̀run, OLORUN wà níbẹ̀!
Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá OLODUMARE níbẹ̀.

If I go up to the heavens, YOU are there; if I make my bed in the depths, YOU are there.
Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá, kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí,
If I rise on the wings of the dawn if I settle on the far side of the sea,
Níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ OLODUMARE ni yóo máa tọ́ mi,
tí ọwọ́ ọ̀tún OLORUN yóo sì dì mí mú.

Even there YOUR hand will guide me, YOUR right hand will hold me fast.
Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀, kí ọ̀sán di òru fún mi,
If I say, “Surely the darkness will hide me and the light become night around me,”
òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún OLUWA;
òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; lójú OLODUMARE, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn.

even the darkness will not be dark to YOU; the night will shine like the day, for darkness is as light to YOU.
Nítorí OLUWA ni o dá inú mi,
OLUWA ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi.
For YOU created my inmost being; YOU knit me together in my mother’s womb.
Mo yìn OLUWA, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni wọ́n;
ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n! OLUWA mọ̀ mí dájú.

I praise YOU because I am fearfully and wonderfully made; YOUR works are wonderful, I know that full well.
Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀, tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí, kò sí èyí tí ó pamọ́ fún OLODUMARE.
My frame was not hidden from YOU when I was made in the secret place, when I was woven together in the depths of the earth.
Kí á tó dá mi tán ni OLORUN ti rí mi,
OLORUN ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi
sinu ìwé wọ́n, kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.

YOUR eyes saw my unformed body; all the days ordained for me were written in YOUR book before one of them came to be.
ỌLORUN, iyebíye ni èrò YIN lójú mi!
Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye.

How precious to me are YOUR thoughts,GOD! How vast is the sum of them!
Bí mo bá ní kí n kà wọ́n, wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ.
Were I to count them, they would outnumber the grains of sand—

H A L L E L U J A H ! ! !


My love had a vineyard
On a fertile hillside
He dug it up and cleared it of stones
And planted it with the choicest vines

He worked the desert into a pool of water
He worked until the dry land turned into springs of water
He made rivers flow on the barren heights
And fountains in the middle of the valleys
He turned the desert into pools of water
And a parched land into springs of water

He plucked up the weeds and killed the caterpillars
He fortified the garden and fenced it round about
He fixed an iron gate and a bronze wall about it
He built a watchtower in it
And cut out winepress as well.

He guarded the garden always;
And satisfied its needs in a sun-scorching season
Then one day!
He looked for a crop of good grapes,
But it yielded only bad ones.

“Now you dwellers in the land,
Judge between me and my vineyard
What more could I have done for my vineyard
Than I have done for it?
When I looked for good grapes,
Why did it yield only bad?’’

‘‘Now I will tell you
What I am going to do to my vineyard:
I will take away its fences,
And it will be destroyed;
I will break down its wall,
And it will be trampled.
I will make it a wasteland,
Neither pruned nor cultivated,
And briers and thorns will grow there.
I will command the clouds
Not to rain on it.”

Who is this vineyard?
H A L L E L U J A H ! ! !


  1. OLUWA ỌLORUN tí ó mí sinu àwọn wolii rẹ̀ / LORD GOD of the Holy Prophets Rev. 22:6
  2. OLUWA OLORUN orí òkè Sinai / LORD GOD of Mount Sinai Neh. 9:13
  3. OLUWA JESU KRISTI / LORD JESUS CHRIST Acts 2:36
  4. JESU KRISTI, OLUWA tí ó lógo / LORD JESUS CHRIST LORD of Glory James 2:1
  5. OLUWA ati Mesaya!” / LORD Messiah Acts 2:36
  6. OLUWA, Ọ̀gá Ògo julọ / LORD Most High Psalms 7:17
  7. Àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun / LORD YHWH Everlasting Strength Isa. 26:4
  8. OLUWA o ni majẹmu titun /LORD of a New Covenant Jer. 31:31. Heb. 8
  9. OLUWA gbogbo eniyan / LORD of All Acts 10:35
  10. OLUWA tí ó lógo /LORD of Glory I Cor. 2:8
  11. Àlàṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé / LORD of Heaven and Earth Matt. 28:18. Acts 17:24
  12. OLUWA àwọn ọmọ ogun /LORD of Hosts Isa. 23:9
  13. OLUWA àwọn ọba aye / LORD of Kings Dan. 2:47
  14. OLUWA àwọn oluwa / LORD of Lords Deut. 10:11
  15. OLUWA alaafia / LORD of Peace II Thess. 3:16. John 4:35
  16. ỌLORUN ti o ni gbogbo ọlá ni ọrun /LORD of Heavens Riches Romans 10:12
  17. OLUWA ìkórè / LORD of the Harvest Matt. 9:38. John 4:35
  18. OLUWA Ọjọ́ Ìsinmi / LORD of the Sabbath Mark 2:28
  19. OLUWA gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ lati ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii / LORD of the Scriptures John 5:39-40. Luke 24:27
  20. OLUWA ti o n bọ wa ni eekeji / LORD of the Second Advent Heb. 9:28. Titus 2:15
  21. OLUWA àgbáyé / Lord of the Whole Earth Micah 4:13
  22. ỌLORUN ìrètí wa / LORD Our Hope I Tim. 1:1
  23. OLUWA ni onídàájọ́ wa / LORD Our Judge Isa. 33:22. John 5:29
  24. OLUWA ni ọba wa / LORD Our KING Isa. 33:22
  25. OLUWA ni alákòóso (olófin)wa / LORD our lawgiver Isa. 33:22
  26. OLUWA, OLUWA wa / LORD Our LORD Psa. 8:1,9
  27. OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa / LORD Our Maker Psa. 95:6
  28. OLUWA ni òdodo wa / LORD Our Righteousness Jer. 23:6
  29. Ẹ̀ka olódodo / Righteous Branch; Jer. 23:5
  30. OLUWA ni ààbò wa / LORD Our Shield Psa. 3:3; 59:11
  31. OLUWA gbogbo agbaye / LORD Over All Romans 10:12. Phil. 2:11
  32. OLUWA ỌLORUN àwọn ọmọ ogun / LORD the GOD of Hosts Amos 6:8
  33. OLUWA, Olùràpadà rẹ / LORD Thy Redeemer Isa. 60:16
  34. OLUWA, Olùgbàlà, ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu /LORD Thy Savior Acts 4:12; 60:16
  35. Olufẹ́ràn òdodo / Lover of Righteousness Heb. 1:9. Psa. 33:5
  36. OLUWA tí o tóbiju / Magnified LORD Isa. 34:3
  37. Orúkọ tí o tóbiju; tí o fìdí múlẹ̀ / Magnified Name I Chron. 17:24
  38. ògo ọlá ńlá RẸ̀ / Majesty Isa. 2:19
  39. Ẹ̀ledáá ohun gbogbo / Maker of All Things John 1:3. Col. 1:16
  40. OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹl /Holy ONE of Israel Isa. 45:11
  41. OLUWA, ẹlẹ́dàá rẹ / Maker of Israel Hosea 8:14 Isa. 45:11
  42. ỌLORUN ní ń sọ òwúrọ̀ di òru /Maker of Morning Darkness Amos 4:13
  43. OLORUN tí o dà ẹ̀dá titun kan náà ninu ara rẹ̀ (Ọ̀kan ninu KRISTI) /Maker of One New Man Eph. 2:15
  44. Ẹ̀lẹ́dàá Alaafia / Maker of Peace Eph. 2:15
  45. Olulana ona iye titun / Maker of the New Way Isa. 43:14. Matt. 27:58
  46. OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun /Maker of the Path in the Sea Isa. 43:16. Exo. 14:21; 15:10
  47. OLUWA tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá / HE made a path through the mighty waters Isa. 43:16
  48. KRISTI JESU, tí òun náà jẹ́ eniyan / Man Christ Jesus I Timothy 2:5
  49. Eniyan ỌLORUN / Man of God Judges 13:6
  50. Ẹ̀niti Àwọn eniyan kẹ́gàn / Man of Sorrows Isa. 53:3. John 19:16

H   A   L   L   E   L   U   J   A   H   !   !   !


  1. Ẹni Mímọ́ / Kodashim (Holy One) Proverbs 9:10; 30:3
  2. Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè lọpọlọpọ jú gbogbo eniyan lórí ilẹ̀ alààyè / The HOLY ONE with infinite wisdom
  3. Irúbọ ẹ̀ṣẹ̀ / Korban (Sacrifices) Heb. 9:28
  4. Ọ̀dọ́ Aguntan/ Lamb Rev. 5:6; 13:8
  5. Ọ̀dọ́ Aguntan ỌLORUN / Lamb of GOD John 1:29, 36
  6. Ọ̀dọ́ Aguntan lórí òkè Sioni / Lamb of Mount Zion Rev. 14:2
  7. Ọ̀dọ́ Aguntan Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji Eniyan Israẹli / Lamb of 144,000 Rev. 7:5-8
  8. Ọ̀dọ́ Aguntan ìgbàlà / Lamb of Salvation Rev. 7:10
  9. ỌLORUN wa tí ó jókòó lórí ìtẹ́, / GOD who sits on the throne, Rev. 7:10
  10. Ọ̀dọ́ Aguntan gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà, ati oríṣìíríṣìí èdè / Lamb of the Great Multitude Rev. 7:9
  11. Ọ̀dọ́ Aguntan ti àwọn aposteli mejila / Lamb of the Twelve Apostles Rev. 21:14
  12. Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé / Lamb Slain from the Foundation Rev. 13:8
  13. Ọ̀dọ́ Aguntan tí wọn pa ni ipakupa/ Lamb to the Slaughter Isa. 53:7. Acts 8:32
  14. Ọ̀dọ́ Aguntan tí ni abawọn, alebu tabi abuku tí kó si lè bàjẹ́ / Lamb Without Spot and Blemish I Peter 1:18
  15. OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi / Lamp II Sam. 22:29
  16. Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi / Lamp of the Feet Psa. 119:105
  17. Adamu ìkẹyìn tí ó ń sọ eniyan di alààyè / Last Adam I Cor. 15:45
  18. Olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè. / Leader and Commander Isa. 55:4
  19. Ìyè / Life John 1:4
  20. Ìyè aráyé / Life of Man Gen. 1:26. John 1:14
  21. Ọmọ ti a gbesókè, Eni agbega ati igbeleke / Lifted and Exalted Son John 3:14; 8:28
  22. Eniti gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan fun ijiya / Lifted Up Suffering Symbol Num. 21:9
  23. OLUWA ni ààbò mi / GOD is my shield
  24. ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. / Lifted of My Head Psa. 3:3; 110:7
  25. ààbò mi / My shield Psa. 3:3
  26. ògo mi / My glory Psa. 3:3
  27. Ìmọ́lẹ̀ ati òtítọ́ ọ́nà mi / Light and Truth Psalms 43:3
  28. Ìmọ́lẹ̀ ayeraye / Light Everlasting Isa. 60:20
  29. Ìmọ́lẹ̀ fún olódodo ninu òkùnkùn / Light in Darkness Psa. 112:4. John 8:12
  30. Ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run tí ó mọ́lẹ̀ ju ti oòrùn lọ / Light of Heaven Acts 26:13
  31. Ìmọ́lẹ̀ Israeli / Light of Israel Psa. 10:17
  32. Ìmọ́lẹ̀ aráyé / Light of Men John 1:4
  33. ỌLORUN ni ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí Ìlú náà; Ọ̀dọ́ Aguntan ni àtùpà ibẹ̀ / Light of the City Rev. 21:23
  34. ìmọ́lẹ̀ aráyé / Light of the Gentiles Isa. 42:6. Luke 2:39
  35. ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere / Light of the Glorious Gospel II Cor. 4:4
  36. ìmọ́lẹ̀ tí ó logo OLORUN / Light of the Glory of God II Cor 4:4. John 17:5
  37. òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà / Light of the Path Psa. 110:105
  38. ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè / Light of the World John 8:12; 9:5
  39. ìmọ́lẹ̀ ojurere OLUWA / Light of Thy Countenance Psa. 89:15
  40. Kinniun ẹ̀yà Juda / Lion of the Tribe of Judah Hos. 11:10. Rev. 5:5
  41. Kinniun Sioni, / Lion of Zion Joel 3:16
  42. Oúnjẹ ìyè / Living Bread John 6:51
  43. Olùdáǹdè to ń bẹ láàyè / Living Redeemer Job 19:25
  44. Olùgbala to ń bẹ láàyè / Living Savior Romans 5:9-11
  45. Òkúta Ààyè / Living Stone I Peter 2:4
  46. ỌLORUN ti kì í tètè bínú, / Longsuffering GOD Num. 14:18. Psa. 86:15
  47. OLORUN ati KRISTI / LORD and CHRIST Acts 2:36
  48. OLUWA ati OLORUN / LORD and GOD John 20:28; 10:30
  49. OLUWA ati Olu-oluso aguntan / LORD and Shepherd Psa. 23:1
  50. OLUWA lati orun wa / LORD From Heaven I Cor. 15:47


1. Òkúta iyebíye/Jasper and Sardine Stone Rev. 4:3
2. ỌLỌRUN owú /Jealous GOD Exo. 20:5. Joshua 24:19
3. JESUS KRISTI, ỌLỌRUN wa / JESUS CHRIST our LORD Matt. 1:1
4. JESUS KRISTI i Olùgbàlà wa / JESUS CHRIST our Saviour Titus 2:6
5. JESU KRISTI olódodo /JESUS CHRIST the Righteous I John 2:1
6. Alágbàwí kan pẹlu Baba / An advocate with the FATHER 1 John 2:1
7. Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa /HE is the atoning sacrifice for our sins 1 John 2:2
8. JESU tí a kàn mọ́ agbelebu / JESUS the Crucified Acts 2:36
9. OLUWA ati MESAYA /LORD and MESSIAH Acts 2:36
10. JESU KRISTI ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ /JESUS the Grace and Truth John 1:17
11. Onídàájọ́/Judge Psa. 50:6
12. Onìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;/Judge Among Nations Isa. 2:4
13. Onídàájọ́ gbogbo Ayé/Judge of All the Earth Gen. 18:25
14. On ìdájọ́ alààyè ati òkú/Judge of Quick and Dead 1 Peter 4:5, 2 Timothy 4:1
15. Olu ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbaba/Judge of the Fatherless Psa. 10:18
16. Olùgbèjà àwọn opó/Judge of Widows Psa. 68:5. Luke 21:1-4
17. Olùpèsè ibùjókòó fún àlejò/ Maker of home for the lonely; Psa. 68:6
18. Ẹnití ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra / HE leads out the prisoners into prosperity; Psa. 68:6
19. Ẹnití ỌLỌRUN dá láre ninu ẹ̀mí,/Justified of the Spirit I Tim. 3:16
20. Oludaláre àwọn tí ó kọlà nípa igbagbọ /Justifier of the Circumcision Romans 3:30
21. Ẹnití yóo mu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun, wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA. /Justifier of the Seed of Israel Isa. 45:25
22. ỌLỌRUN olòdodo /Just GOD Isa. 45:25
23. OLUWA olòdodo /Just LORD Zeph. 3:5
24. ỌLỌRUN ati olódodo,/Just ONE Acts 3:14; 7:52
25. ỌLỌRUN Olùgbàlà/Just Saviour Isa. 45:21
26. Aláàbò ati Olupamọ́ Israẹli /Keeper of Israel Psa. 121:4
27. ỌLỌRUN tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, ỌLỌRUN tí ó bani lẹ́rù/ The great GOD, mighty and awesome, Neh. 9:32
28. ỌLỌRUN tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, /Keeper of the Covenant and Mercy Neh. 9:32
29. Ẹni mímọ́ ati olóòótọ́ nì / Holy and True Rev. 3:7
30. Ẹnití ó kọ́kọ́rọ́ Dafidi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ / HE holds the key of David Rev. 3:7
31. Ẹnití ó ṣí ìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè tì í / What HE opens no one can shut, Rev. 3:7
32. Ẹnití ó sìí tìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí / What HE shuts no one can open Rev. 3:7
34. Atan iná ńlá tí ń jó ọpọlọpọ/Kindler of Tophet Isa. 30:33. Matt. 25:41
35. Olutọju àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú /Keeper of the Keys of Hell and Death Rev. 3:18
36. ỌBA ọlọlá ńlá /KING Beautiful Isa. 33:17
37. ỌBA ayérayé/KING Eternal I Tim. 1:17
38. ỌBA lae ati laelae./KING Forever Psa. 10:16
39. ỌBA gbogbo ayé /KING of All the Earth Psa. 47:7
40. ỌBA ògo /KING of Glory Psa. 24:7-10
41. ỌBA ọ̀run /KING of Heaven Dan. 4:37
42. ỌBA àwọn ọba ati OLUWA àwọn olúwa /KING of Kings and LORD of Lords Rev. 19:16
43. ỌBA àwọn orílẹ̀-èdè /KING of Nations Jer. 10:10. Rev. 12:5
44. ỌBA alaafia/KING of Peace Heb. 7:2
45. ỌBA òdodo /KING of Righteousness Heb. 7:2
46. ỌBA àwọn Ẹni mímọ́ /KING of Saints Rev. 15:3
47. ỌBA olòtítọ́ /KING of Truth John 18:37
48. ỌBA òtítọ́ /KING of Zion Psa. 2:6. Zech. 9:4
49. Ìbátan tí ó súnmọ́ ni /Kinsman Nearer Than I Ruth 3:12
50. Ìbátan ati Olùdáǹdè /Kinsman Redeemer Job 19:25. John 1:11
H A L L E L U J A H ! ! !


Iba o! iba!! / Worship…… Worship….
Iba JESU KRISTI ti n be lokan aya BABA The Creator of heaven and earth
Ọba ti o n ṣe iyanu laini iye /HE does marvellous things without number
Ọba ti o yi imọ awọn alarekereke po /HE disappoints the devices of the crafty
Ọlọgbọn ninu ati alagbara ni ipa /HE is wise in heart and mighty in strength
Ọba ti o ṣi oke ni idi, ti oke o si si mọ /HE removed the mountains and the mountains did not know..
Ọba ti omi ilẹ aye titi kuro ni ipo rẹ/ HE shook the earth out of her place LORD
Ọba ti o nrin lori igbi / HE walk on the waves of the sea
alatunṣe ni agbedemeji aye ati ọrun /THE only DAYSMAN between the heaven and the earth)
Oluwosan àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ọkan / Healer of Broken Hearts Isa. 61:1. Psalms 51:17
Olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba / Helper of the Helpless Psa. 10:14.
Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ / High and Lofty One Isaiah 57:15
Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa / High Priest of Our Profession Heb. 3:1; 6:20
Dídán ìtànṣán Ọlọrun / His Brightness Habbakuk 3:4
Ilekun ńláńlá / Great Door
Àsíá ati àmì / Ensign Isa. 30:17
Opagun Ifẹ / Banner of Love Song of Solomon 2:4
Olú olùṣọ́-aguntan / Great Shepherd. Heb. 13:20 Psa 23:1
Àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú / First Fruits of Them That Slept I Cor. 15:20
Ìfẹ́ Àkọ́kọ́ / First Love I John 4:19
Ayọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé l’ọjọ iponju / Hope in Day of Evil Jer. 17:7 3:7
ìrètí ògo / Hope of Glory Col. 1:27
Ìrohin ayọ̀ idande/ Goodnews of redemption
àrólé ohun gbogbo / appointed heir of all things Heb. 1:9
ẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Ọlọrun / Fullness of the Godhead Col. 2:9
Ohun ògo / Excellent Isa 4:2
Ohun àmúyangàn / Comely One Isa. 4:2
Alàṣẹ áti onìdájọ́ / Executor of Judgment John 5:27
Kòríkòsùn Baba / Face of God John 1:18
Asoju Olóòótọ́ / Faithful Ambassador Proverbs 13:7
Ìmúpadàbọ̀sípò onigbagbo / Redeemer Job 19:25
Olorúkọ olókìkí títí lae / Everlasting name Isa 63:12
Ẹlẹ́rìí òtítọ́ / Faithful Witness Rev. 1:5
Alákòóso / General overseer Zech. 3:17
ìri ewe / Dew of youth Psalms 110:3
Ade ẹwà/ Diadem of Beauty Isa. 28:5
Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ onigbagbo / Help of believer

Mímọ́ mímọ́ mímọ́ / Holy holy holy
OLUWA mímọ́ / Holy and True Rev. 6:10
Ọlowọ́ agbara mimo / His Holy Arm Isaiah 52:10
Olorúkọ mímọ́ / Holy Name Psa. 33:21
Onidajọ́ mímọ́ / Righteous judge
Ẹnì ayérayé jókòó lórí itẹ̀ mímọ́ / A throne was set in heaven, and one sat on the throne.
Ojú wọ́n dàbí òkúta iyebíye / HE that sat was to look upon like a jasper and a sardine stone
Wọ́n wọ aṣọ ẹ̀wù funfun tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀ / Clothed with a garment down to the foot
Wọ́n fi ọ̀já wúrà gba àyà / with a golden girdle about his bust
Irun orí wọ́n funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú / HIS head and his hairs were white like wool, as white as snow
Ojú wọ́n ń kọ yànràn bí iná / HIS eyes were as a flame of fire
Ojú wọ́n mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan / HIS countenance was as the sun shines in his strength
Ẹsẹ̀ wọ́n dàbí idẹ tí ń dán / HIS feet like unto fine brass
Ohùn wọ́n dàbí híhó omi òkun / HIS voice as the sound of many waters.
Idà olójú meji tí ó mú n yọ jáde lẹ́nu wọ́n / Out of his mouth went a sharp twoedged sword
Ìtẹ́ OLORUN ń jó bí ahọ́n iná / HIS throne was like the fiery flame
Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, / There was a rainbow round about the throne, in sight like unto an emerald.
ìtẹ́ mẹrinlelogun yí ìtẹ́ OLORUN ká / Round about the throne were four and twenty seats
Àwọn Àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ / Upon the seats I saw four and twenty elders sitting,
Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ OLORUN / Out of the throne proceeded lightnings and thunderings and voices
Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin yí ìtẹ́ ká / In the midst of the throne, and round about the throne, were four beasts full of eyes before and behind.
Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun iranṣẹ / Thousand thousands ministered unto him,
ọ̀kẹ́ àìmọye sì dúró níwájú OLORUN / Ten thousand times ten thousand stood before him
Pelu duru ati ago wura / with the harp and their vials
Wọ́n nkọ mímọ́ mímọ́ mímọ́ / they sang holy holy holy
Mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ / I have questions for you, and I want you to answer me
Níbo lo wà, nígbà tí OLORUN OLODUMARE fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? / “Where were you when GOD laid the earth’s foundation?
“Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí / “Have you ever journeyed to the springs of the sea
Tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí? / Or walked in the recesses of the deep?
Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí / Have the gates of death been shown to you?
Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun?/ “Can you discover the depths of GOD?
Tabi kí o tọpinpin Olodumare? ” / Can you discover the limits of the Almighty?

“Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí OLORUN ń kó yìnyín pamọ́ sí rí / “Have you ever entered the storehouses of the snow
“Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò / Who cuts a channel for the torrents of rain?
Ati fún ààrá/ and a path for the thunderstorm,
Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì? / Does the rain have a father? Who is the father of dew?
Ìyá wo ló bí yìnyín / From whose womb comes the ice?
Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùu / Who gave the clouds their wisdom?
Ati ìmọ̀ sinu ìrì? / Or gave understanding to the dew?
Ṣé ẹ kò tíì mọ̀? / Have you not known?
Ṣé kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé / Haven’t you understood from the foundations of the earth?
OLORUN OLODUMARE ni ó jókòó lókè àyíká ayé / It is HE that sits upon the circle of the earth,

Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ, kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí OLODUMARE / GOD is great—HE is beyond our understanding! The number of his years is past finding out.
ỌBA to pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni won pase fun òjò wẹliwẹli, ati ọ̀wààrà òjò / HE says to the snow, ‘Fall on the earth; likewise to the small rain, and to the great rain of his strength.
ỌBA to pàṣẹ ti Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀, òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ / HE commanded the whirlwind to come out of its room and cold out of the north.

Eyin ara ipejopo Ore-ofe/People of Grace Assembly
Ìró ààrá ń kéde bíbọ̀ JESU KRISTI / HIS thunder announces the coming of JESUS CHRIST
Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún /Just as you do not know the path of the wind and how bones are formed in the womb of the pregnant woman
Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, / Indeed, if a man should live many years, let him rejoice in them all
ọjọ́ tí yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ / and let him remember the days of darkness, for they will be many.

Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀/ Let the one who does wrong, still do wrong
Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀/ and the one who is filthy, still be filthy
Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.”/ and let the one who is righteous, still practice righteousness; and the one who is holy, still keep himself holy.”
Iwe ifihan ori ikejilelogun ese ikokanla so wipe/ Revelations 22:11 says
“Mò ń bọ̀ ní kíá / Behold, I am coming quickly,
Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi / and My reward is with Me,
tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí / to render to every man according to what he has done.
Emura! Emura!! Emura!!!/ Be prepared
JESU ti fere de / JESUS is coming soon

H A L L E L U J A H ! ! !


Welcome to ThepraisesofGod.wordpress.com. There are over 120 posts on just Praises of GOD / Oriki OLODUMARE. check out our Yoruba translations.


1.ỌLỌRUN nìkan ni orísun ire mi / GOD alone is the fountain of my goodness Psalm 16:2
2. OLUWA, ni ayọ̀ kíkún mi / The LORD is Fullness of joy Psalm 16:11
3.OLUWA, ni ìgbádùn àìlópin / The LORD is my Eternal pleasures Psalm 16:11
4.OLUWA, ni Ìpín mi / The LORD is my portion Psalm 16:5
5.OLUWA ogún rere mi / The LORD is my inheritance Psalm 16:5
6. Ẹni Mímọ́ / Holy One Job 6:10
7. Ẹni Mímọ́ olóòótọ́ ati olódodo / Holy ONE and Just Acts 3:14
8. Ẹni Mímọ́ ỌLỌRUN / Holy One of GOD Mark 1:24
9. Ẹni Mímọ́ Israẹli / Holy One of Israel Isa. 41:14
10. Ẹni Mímọ́ Jakọbu / Holy One of Jacob Isa. 29:23
11. Ọdọ-aguntan Mímọ́ ti o ni Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá / Honorable Lamb of Glory Rev. 7:12
12.Ọmọ BABA tí á bu ọlá fún / Honored Son John 5:23
13. Ayọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé l’ọjọ iponju ati ní ìgbà ìṣòro / Hope in Day of Evil Jer. 17:7
14. Ìgbẹ́kẹ̀lé Dafidi / Hope of David Psa. 16:19
15. Ìgbẹ́kẹ̀lé ati ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun / Hope of Eternal Life Titus 3:7
16. Ìgbẹ́kẹ̀lé ati ìrètí ògo / Hope of Glory Col. 1:27
17. Ìgbẹ́kẹ̀lé ati ibi ààbò fún Israẹli / Hope of His People Israel Joel 3:16
18. Ìgbẹ́kẹ̀lé Ìwọ ìrètí Israẹli, OLUGBALA (Olùgbàlà) rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro /Hope of Israel Jer. 14:8
19. Ìgbẹ́kẹ̀lé ati iretí ìdáláre nípa igbagbọ / Hope of Righteousness Gal. 5:5
20. Ìgbẹ́kẹ̀lé atí ìrètí pé ìlérí tí ỌLỌRUN ṣe fún àwọn baba wa yóo ṣẹ / Hope of the Promise Acts 26:6
21. Ìgbẹ́kẹ̀lé atí ìrètí ayọ̀ kíkún fún Abrahamu / Hope and Joy of Abraham John 8:56
22. Ìgbẹ́kẹ̀lé atí ìrètí ayọ̀ kíkún fún / Hope and Joy of Simeon Luke 2:25-32
23.Ìwo Dafidi / Horn of David Psa. 132:17
24.Ìwo ìgbàlà / Horn of Salvation Luke 1:69
25.Ìwo fún ilé Dafidi / Horn of the House of David Eze. 29:21
26.Ìwo fún ilé Israeli / Horn of the House of Israel Eze. 29:21
27.Ìwo ìgbàlà mi / Horn of My Salvation Psa 18:2. II Sam. 22:23
28. Hosana ní òkè ọ̀run!” / Hosanna of the Highest Praise Mark 11:10
29.Àpáta ààbò fún mi / Rock of my defence Psa. 31:2
30.Ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là / House of Defense Psa. 31:2. Zech. 9:9
31.Àpáta ayérayé ni OLUWA ỌLỌRUN / Rock of Ages Isa 26:5
32. Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀, ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀, ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata, ó fà á sọ sinu eruku / Humbler of the High Minded Isa. 26:5
33. Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ Israeli / Husband of Israel Isa. 54:5
34.Ọkọ iyawo / Husband of the Bride Rev. 21:2. Jer. 23:9. II Cor. 11:2
35.“ÈMI NI’’ / ‘‘I Am’’ John 8:58
36. “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́ / ‘‘I Am that I Am’’Exo. 3:14. John 8:58
37.Àwòrán bí ỌLỌRUN tí rí gan-an / Image of GOD Heb. 1:3
38. Àwòrán bí ẹni tí ó mọ̀ ỌLỌRUN / Image of the Believers Col. 3:9
39.Àwòrán BABA / Image of the Father John 14:9
40.Àwòrán ỌLỌRUN ti eniyan kò lè f’oju rí ỌLỌRUN / Image of the Invisible God Col. 1:15
41.Imanuẹli (“ỌLỌRUN wà pẹlu wa.”) / Immanuel Isa. 7:14; 8:10. Matt. 1:23
42.ỌBA àìkú / Immortal I Tim. 1:17
43. ỌLỌRUN tí ó ji dide Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan / Incarnate GOD John 1:14
44.OLUWA wà títí lae, láti ìran dé ìran / Infinite One Psa. 33:11. Mal. 3:16
45. Ajogun gbogbo orílẹ̀-èdè! Tì OLUWA ni gbogbo orílẹ̀-èdè / Inheritor of All Nations Psa. 82:8
46.Àjogún òkè ńlá mi / Inheritor of My Mountains Isa. 65:9
47. ẸNI tí n bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ / Intercessor of Sinners Isa. 53:12
48.ỌLỌRUN tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA ỌLỌRUN rẹ / Jealous GOD Exo. 20:5. Joshua 24:19
49.Ẹka tí ó ni ògo / Beautiful branch Isa. 4:2
50.Ẹka àmúyangàn / Glorious branch Isa. 4:2

H A L L E L U J A H ! ! !