Posts Tagged ‘oriki Olorun’



Jagunjagun l’Oluwa is a Folkloric track musical that expresses the awesome majesty of an invincible GOD – HIS sovereignty, holiness, and knowledge, in large part through oral communication, Yoruba traditional chants, musical drama, and storytelling.


Hello everyone!

It’s been an awesome journey for me since www.thepraisesofGod.com was launched on this platform. THANK YOU for being a part of the history of this blog. I couldn’t have wished for a better audience. The thirst for more Praise and worship songs gave birth to ORIKI OLORUN OLODUMARE volume 1 and that opened a whole new chapter of my life that I didn’t know existed.

www.thepraisesofGod.com  is announcing the release of ORIKI OLORUN OLODUMARE volume 1.

It’s a 10-Track Folkloric Album musical that expresses the awesome majesty of an invincible GOD – HIS sovereignty, holiness, and knowledge, in large part through oral communication, Yoruba traditional chants, musical drama, and storytelling. The only English song in the album is a call to complete surrender to the mysterious power of the ALMIGHTY GOD.

ORIKI OLORUN OLODUMARE volume 1 is a complete spiritual yet entertainment album where all musical and lyrical ideas infused to a single overall description of the ALMIGHTY GOD. It is predominantly described by the term ‘NEW CONCEPT’ by my release audience.  It was recorded in Abu Dhabi, United Arab Emirates and mixed in Nigeria. The lyrics and chants are literarily taken out of the Holy Bible. The songs are produced by Mr Olabode Afolabi.

The music video of one of the songs ‘JAGUNJAGUN L’OLUWA’ a sub-genre of epic film, written by me and to be directed by the award-winning Nigeria Movie Director; Funke Fayoyin will be out soon.

I’ll post snippets of the songs before the year runs out.

I’ll work harder to post more on ORIKI OLORUN OLODUMARE.

Thank you so much for urging me on.

Best regards always,

Bolanle Ojo



1. Òkúta iyebíye/Jasper and Sardine Stone Rev. 4:3
2. ỌLỌRUN owú /Jealous GOD Exo. 20:5. Joshua 24:19
3. JESUS KRISTI, ỌLỌRUN wa / JESUS CHRIST our LORD Matt. 1:1
4. JESUS KRISTI i Olùgbàlà wa / JESUS CHRIST our Saviour Titus 2:6
5. JESU KRISTI olódodo /JESUS CHRIST the Righteous I John 2:1
6. Alágbàwí kan pẹlu Baba / An advocate with the FATHER 1 John 2:1
7. Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa /HE is the atoning sacrifice for our sins 1 John 2:2
8. JESU tí a kàn mọ́ agbelebu / JESUS the Crucified Acts 2:36
9. OLUWA ati MESAYA /LORD and MESSIAH Acts 2:36
10. JESU KRISTI ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ /JESUS the Grace and Truth John 1:17
11. Onídàájọ́/Judge Psa. 50:6
12. Onìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;/Judge Among Nations Isa. 2:4
13. Onídàájọ́ gbogbo Ayé/Judge of All the Earth Gen. 18:25
14. On ìdájọ́ alààyè ati òkú/Judge of Quick and Dead 1 Peter 4:5, 2 Timothy 4:1
15. Olu ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbaba/Judge of the Fatherless Psa. 10:18
16. Olùgbèjà àwọn opó/Judge of Widows Psa. 68:5. Luke 21:1-4
17. Olùpèsè ibùjókòó fún àlejò/ Maker of home for the lonely; Psa. 68:6
18. Ẹnití ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra / HE leads out the prisoners into prosperity; Psa. 68:6
19. Ẹnití ỌLỌRUN dá láre ninu ẹ̀mí,/Justified of the Spirit I Tim. 3:16
20. Oludaláre àwọn tí ó kọlà nípa igbagbọ /Justifier of the Circumcision Romans 3:30
21. Ẹnití yóo mu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun, wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA. /Justifier of the Seed of Israel Isa. 45:25
22. ỌLỌRUN olòdodo /Just GOD Isa. 45:25
23. OLUWA olòdodo /Just LORD Zeph. 3:5
24. ỌLỌRUN ati olódodo,/Just ONE Acts 3:14; 7:52
25. ỌLỌRUN Olùgbàlà/Just Saviour Isa. 45:21
26. Aláàbò ati Olupamọ́ Israẹli /Keeper of Israel Psa. 121:4
27. ỌLỌRUN tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, ỌLỌRUN tí ó bani lẹ́rù/ The great GOD, mighty and awesome, Neh. 9:32
28. ỌLỌRUN tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, /Keeper of the Covenant and Mercy Neh. 9:32
29. Ẹni mímọ́ ati olóòótọ́ nì / Holy and True Rev. 3:7
30. Ẹnití ó kọ́kọ́rọ́ Dafidi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ / HE holds the key of David Rev. 3:7
31. Ẹnití ó ṣí ìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè tì í / What HE opens no one can shut, Rev. 3:7
32. Ẹnití ó sìí tìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí / What HE shuts no one can open Rev. 3:7
34. Atan iná ńlá tí ń jó ọpọlọpọ/Kindler of Tophet Isa. 30:33. Matt. 25:41
35. Olutọju àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú /Keeper of the Keys of Hell and Death Rev. 3:18
36. ỌBA ọlọlá ńlá /KING Beautiful Isa. 33:17
37. ỌBA ayérayé/KING Eternal I Tim. 1:17
38. ỌBA lae ati laelae./KING Forever Psa. 10:16
39. ỌBA gbogbo ayé /KING of All the Earth Psa. 47:7
40. ỌBA ògo /KING of Glory Psa. 24:7-10
41. ỌBA ọ̀run /KING of Heaven Dan. 4:37
42. ỌBA àwọn ọba ati OLUWA àwọn olúwa /KING of Kings and LORD of Lords Rev. 19:16
43. ỌBA àwọn orílẹ̀-èdè /KING of Nations Jer. 10:10. Rev. 12:5
44. ỌBA alaafia/KING of Peace Heb. 7:2
45. ỌBA òdodo /KING of Righteousness Heb. 7:2
46. ỌBA àwọn Ẹni mímọ́ /KING of Saints Rev. 15:3
47. ỌBA olòtítọ́ /KING of Truth John 18:37
48. ỌBA òtítọ́ /KING of Zion Psa. 2:6. Zech. 9:4
49. Ìbátan tí ó súnmọ́ ni /Kinsman Nearer Than I Ruth 3:12
50. Ìbátan ati Olùdáǹdè /Kinsman Redeemer Job 19:25. John 1:11
H A L L E L U J A H ! ! !

ORIKI OLODUMARE——PRAISE POETRY

Posted: September 9, 2014 in Praise and Worship
Tags: , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , ,

ORIKI OLODUMARE ( TITLES OF THE ALMIGHTY GOD)

ORIKI OLODUMARE/THE PRAISES OF THE ALMIGHTY GOD

Iba o! iba( Worship…… Worship…..)

Akọda aye aṣẹda ọrun (The Creator of heaven and earth)

Alapa kabikabi ti o n ka ibi kuro niwaju ọmọ won (HE delivers from troubles)

Ọba ti o ṣe ohun ti o tobi (HE does great and wondrous things)

Ọba ti a ko le ṣe awari wọn (HE is unsearchable)

Ọba ti o n ṣe iyanu laini iye (HE does marvelous things without number)

Ọba ti nrọjo si ilẹ aye (HE gives rain upon the earth)

Ọba ti o nran omi sinu ilẹkilẹ (HE sends waters upon the field)

Ọba ti o yi imọ awọn  alarekereke po (HE disappoints the devices of the crafty)

Ọba ti o mu ọlọgbọn ninu arekereke ara won (HE takes the wise in their own craftiness)

Ọlọgbọn ninu ati alagbara ni ipa ni YIN ỌLỌRUN mi (HE is wise in heart and mighty in strength)

Ọba ti o ṣi oke ni idi, ti oke o si si mọ (YOU removed the mountains and the mountains did not know.. hallelujah!)

Ọba ti omi ilẹ aye titi kuro ni ipo rẹ (YOU shook the earth out of her place LORD)

Ọba to paṣẹ fun oorun, ti oorun ko si la (The King who commanded the sun, and it did not rise)

Ọba ti o di irawọ mọ ( YOU seal up the stars)

Ẹnyin nikan ṣoṣo ni o la oju ọrun lọ (YOU spread out the heavens)

Ẹnyin ni kan ni Ọba ti o nrin lori igbi  (YOU walk on the waves of the sea)

Ẹnyin nikan ni alatunṣe ni agbedemeji aye ati ọrun (YOU are the only days man between the heaven and the earth)

Ẹnyin ni ẹ fi awọ ati ẹran-ara wọ  a (YOU clothed us with skin)

Ẹnyin ni ẹ fi egungun ati iṣan ṣọgba yi wa ka (YOU fenced us about with bones and sinew)

 

H   A   L   L   E   L   U   J   A   H   !  !   !

 

 

Akiikitan OLORUN ayeraye …ORIKI OLORUN/PRAISES OF GOD

Posted: September 9, 2014 in Praise and Worship
Tags: , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , ,

Oluwa Oluwa Oluwa awa

Orukọ yin ti ni iyin to ni gbogbo aye
Oriki Ọlọrun ọga ogo;
ẹlẹda ohun gbogbo t’ojoko ni itẹ ogo
Akiikitan Ọlọrun ayeraiye; Atẹrẹrẹkariaye; Iyanu
Alagbala awure; Oludamọran
Ọlọrun alagbara; Baba ayeraye;
Ọmọ alade alafia ; Adiitu Olodumare
Ọba t’ofi ojo-didi fun wa bi awọsanmọ
Ọba t’oda omi didi bi okele
Ẹniti o fi awọsanma bò oju ọrun,
Ẹniti o pèse òjo fun ilẹ,
ti o mu koriko dàgba lori awọn òke nla.
Oluwa nṣe inudidùn si awọn
ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀.
Tani yi o duro niwaju otutu Ọlọrun Olodumare
Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi,
ati gbogbo ibu-omi;
Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;
Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso,
Ẹ yìn orukọ Oluwa
Ẹ yin Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku;
ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;
Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin;
ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò;
Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia;
ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye;
Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia,
awọn arugbo enia ati awọn ọmọde;
Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa;
nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun.
Eyin Oluwa ninu ofurufu oju-ọrun agbara wọn
Awamaridi ni Baba mi; Ọlọrun Oluwa, agbara igbala mi,
Ọlọrun ti o ni iyin pupopupo
Ọba to gbawa kuro ninu ajakalẹ̀ arun
Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọta wa, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè wọn;
ati lati ṣe idajọ wọn oniṣẹ ibi
Ẹda ẹyin iná si wọn lara
Ẹ wọ́ wọn lọ sinu iná, sinu ọgbun omi jijin,
ki nwọn ki o má le dide mọ́.
Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye mi!
Oluwa ọga ogo
Ẹ fi iyìn fun Oluwa
Mimọ́! Mimọ́!! Mimọ́!!!
H A L L E L U J A H ! ! !
Omnipresent GOD; Wonderful
HIS court is full of praises
Counselor; The almighty GOD
The everlasting FATHER; The Prince of peace
The unsearchable GOD
HE gives snow like wool; HE scatters frost like ashes.
HE hurls down his crystals of mice like crumbs;
HE covers the heavens with clouds;
HE prepares rain for the earth; HE makes grass grow on the hills.
HE gives to the beasts their food, and to the young ravens that cry
But the LORD takes pleasure in those who fear him,
In those who hope in HIS steadfast love.
Who can stand before his cold?
Praise the LORDfrom the earth,
You great sea creatures and all deeps,
Fire and hail, snow and mist, Stormy wind fulfilling his word!
Mountains and all hills, and fruit trees
Praise the name of the LORD
Praise the LORD from the earth,
You great sea creatures and all deeps,
Beasts and all livestock, creeping things and flying birds!
Kings of the earth and all peoples,
Princes and all rulers of the earth!
Young men and maidens together, old men and children!
Let them praise the name of the LORD,
For HIS name alone is exalted;
HIS majesty is above earth and heaven.
Praise HIM in the firmament of his power
The greatest unsearchable GOD
My GOD! The strength of my salvation
Great is the LORD, and greatly to be praised
YOU deliver us from deadly diseases and noisome pestilence
To execute vengeance on the nations
And punishments on the peoples,
To bind their enemies with chains and fetters of iron,
To execute on them the judgment written!
Let burning coals fall upon them!
Let them be thrown into fire, into miry pits, no more to rise!
Don’t let the slanderer be established in the land;
Don’t let evil hunt down the violent man speedily!
Praise the LORD
Holy! Holy!! Holy!!!
H A L L E L U Y A H ! ! !

HEBREW NAMES OF GOD, THEIR MEANINGS AND PRONOUNCIATIONS

Posted: September 9, 2014 in Praise and Worship
Tags: , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , ,

This site…http://www.hebrew4christians.com/Names_of_G-d/El/el.html  is a huge blessing to me particularly The Hebrew Names of GOD and I must say it is informative, educative and it’ll just make you want to worship GOD right away. You may also like to check NAMES AND ATTRIBUTES OF JESUS/HOLY SPIRIT and NAMES,ATTRIBUTES,PRAISES OF GOD/ORIKI OLORUN OLODUMARE.

There are over 90 posts on this Blog and 95% of them are on the Praises, Attributes and Names  of GOD. Please enjoy!

ÌYÌN FúN ỌLỌRUN…Praise the LORD! (oriki OLODUMARE)

Posted: September 5, 2014 in Praise and Worship
Tags: , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , ,

Ẹ fi Ìyìn fún ỌLỌRUN

Ọlà ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ ỌLỌRUN mà kúkú jinlẹ̀ pupọ o!
Oh, the depth of the riches both of the wisdom and knowledge of GOD

Àwámárìídìí ni òye ỌLỌRUN OLODUMARE
There is no searching of HIS understanding

Iṣẹ́ ADANIWAYE tayọ ohun tí ẹ̀dá lè tú wò
HIS ways are unfathomable!

Àwámárìídìí ni ìdájọ́ OLODUMARE
How unsearchable are HIS judgments!

“Ta ni mọ inú ỌLỌRUN?
Who knows the mind of the LORD?

Ta ni olùbádámọ̀ràn ỌLỌRUN ọga ogo ?
Who is HIS counselor?

Ta ni ó yá a ní ohunkohun rí tí ó níláti san án pada?
Who has first given to HIM that it might be paid back to him again?

“Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò?
Who cuts a channel for the torrents of rain?

Nítorí lọ́dọ̀ ỌLỌRUN ni ohun gbogbo wà, láti ọwọ́ ỌLỌRUN ni ohun gbogbo ti ń wá, nítorí OLODUMARE sì ni ohun gbogbo ṣe wà
For from HIM and through HIM and to HIM are all things

Ti ỌLỌRUN ni ògo títí ayérayé. Amin
To HIM be the glory forever. Amen.

H A L L E L U J A H ! ! !

ỌLỌRUN ìyanu / Amazing GOD…ORIKI OLODUMARE

Posted: August 27, 2014 in Praise and Worship
Tags: , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , ,

This slideshow requires JavaScript.


JOBU 37
“Fetí sílẹ̀, ìwọ ọrẹ́ mi, dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu ỌLỌRUN
Hearken unto this, my friend: stand still, and consider the wondrous works of GOD
2Gbọ́ ohùn ỌLỌRUN tí ń dún bí ààrá, ati ariwo tí ń ti ẹnu OLODUMARE jáde.
2 Hear attentively the noise of HIS voice, and the sound that goeth out of HIS mouth.
3 ỌLỌRUN ti ó rán mànàmáná jákèjádò ojú ọ̀run, títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
3 HE directeth it under the whole heaven, and HIS lightning unto the ends of the earth.
4 Ìró ohùn ỌLỌRUN sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá wọn, bí ìgbà tí ààrá bá sán, sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúró bí àwọn eniyan ti ń gbóhùn ỌLỌRUN.
4 After it a voice roareth: HE thundereth with the voice of HIS excellency; and HE will not stay them when HIS voice is heard
5Ohùn ỌLỌRUN dún bí ààrá tìyanu-tìyanu, a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu ENI agba ọjọ
5 GOD thundereth marvelously with HIS voice; great things doeth HE, which we cannot comprehend.
6ỌBA to pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli, ati ọ̀wààrà òjò.
6 For HE saith to the snow, Be thou on the earth; likewise to the small rain, and to the great rain of his strength.
7 Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò, kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.
7 HE sealeth up the hand of every man; that all men may know HIS work.
8 Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ, wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́.
8 Then the beasts go into dens, and remain in their places.
9 Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀, òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.
9 Out of the south cometh the whirlwind: and cold out of the north.
10Yìnyín ti inú èémí ỌLỌRUN wá, gbogbo omi inú odò sì dì
10 By the breath of GOD frost is given: and the breadth of the waters is straitened.
11 ỌLỌRUN fi omi kún inú ìkùukùu, ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.
11 Also by watering HE wearieth the thick cloud: HE scattereth HIS bright cloud:
1DSC_00392Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀, láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.
12 and it is turned round about by HIS counsels: that they may do whatsoever HE commandeth them upon the face of the world in the earth.
15Ǹjẹ́ o mọ bí ỌLỌRUN ṣe pàṣẹ, tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?
15 Dost thou know when GOD disposed them, and caused the light of HIS cloud to shine?
16Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ỌLỌRUN ṣe so awọsanma rọ̀, iṣẹ́ ìyanu ENI tí ó pé ní ìmọ̀ ni;
16 Dost thou know the balancings of the clouds, the wondrous works of HIM which is perfect in knowledge?
17Ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́ nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?
17 How thy garments are warm, when HE quieteth the earth by the south wind?
18Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ỌLỌRUN ti tẹ́ ẹ, kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán?
18 Hast thou with HIM spread out the sky, which is strong, and as a molten looking-glass?
21“Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run nígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma, nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.
21 And now men see not the bright light which is in the clouds: but the wind passeth, and cleanseth them.
22Láti ìhà àríwá ni ỌLỌRUN ti yọ, ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.
22 Fair weather cometh out of the north: with GOD is terrible majesty.
23Àwámárìídìí ni Olodumare– agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ỌLỌRUN kì í kọ òdodo sílẹ̀.
23 Touching the Almighty, we cannot find him out: HE is excellent in power, and in judgment, and in plenty of justice: HE will not afflict.
H A L L E L U J A H ! ! !

ỌLỌRUN oníṣẹ́ àrà / GOD of wonders ….ORIKI OLODUMARE

Posted: August 18, 2014 in Praise and Worship
Tags: , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , , ,


Please check the other posts. There are over 110 of them on the ORIKI OLODUMARE.

JOB 36

26Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ, kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí rẹ̀.
26 How great is God–beyond our understanding! The number of his years is past finding out.

27“Ó fa ìkán omi sókè láti inú ilẹ̀, ó sọ ìkùukùu di òjò,
27 “He draws up the drops of water, which distill as rain to the streams

28 ó sì rọ òjò sílẹ̀ láti ojú ọ̀run sórí ọmọ eniyan lọpọlọpọ.
28 the clouds pour down their moisture and abundant showers fall on mankind.

29Ta ló mọ bí ó ti tẹ́ ìkùukùu? Tabi bí ó ṣe ń sán ààrá láti inú àgọ́ rẹ̀?
29 Who can understand how he spreads out the clouds, how he thunders from his pavilion?

30 Ó fi mànàmáná yí ara rẹ̀ ká, ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.
30 See how he scatters his lightning about him, bathing the depths of the sea.

31Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè; ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ lọpọlọpọ.
31 This is the way he governs the nations and provides food in abundance.

32Ìkáwọ́ rẹ̀ ni mànàmáná wà, ó sì ń rán ààrá láti sán lu ohun tí ó bá fẹ́.
32 He fills his hands with lightning and commands it to strike its mark.

33Ìró ààrá ń kéde bíbọ̀ rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn sì mọ̀ pé ó súnmọ́ tòsí.
33 His thunder announces the coming storm; even the cattle make known its approach.

H A L L E L U J A H ! ! !