Iba o! iba!! / Worship…… Worship….
Iba JESU KRISTI ti n be lokan aya BABA The Creator of heaven and earth
Ọba ti o n ṣe iyanu laini iye /HE does marvellous things without number
Ọba ti o yi imọ awọn alarekereke po /HE disappoints the devices of the crafty
Ọlọgbọn ninu ati alagbara ni ipa /HE is wise in heart and mighty in strength
Ọba ti o ṣi oke ni idi, ti oke o si si mọ /HE removed the mountains and the mountains did not know..
Ọba ti omi ilẹ aye titi kuro ni ipo rẹ/ HE shook the earth out of her place LORD
Ọba ti o nrin lori igbi / HE walk on the waves of the sea
alatunṣe ni agbedemeji aye ati ọrun /THE only DAYSMAN between the heaven and the earth)
Oluwosan àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ọkan / Healer of Broken Hearts Isa. 61:1. Psalms 51:17
Olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba / Helper of the Helpless Psa. 10:14.
Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ / High and Lofty One Isaiah 57:15
Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa / High Priest of Our Profession Heb. 3:1; 6:20
Dídán ìtànṣán Ọlọrun / His Brightness Habbakuk 3:4
Ilekun ńláńlá / Great Door
Àsíá ati àmì / Ensign Isa. 30:17
Opagun Ifẹ / Banner of Love Song of Solomon 2:4
Olú olùṣọ́-aguntan / Great Shepherd. Heb. 13:20 Psa 23:1
Àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú / First Fruits of Them That Slept I Cor. 15:20
Ìfẹ́ Àkọ́kọ́ / First Love I John 4:19
Ayọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé l’ọjọ iponju / Hope in Day of Evil Jer. 17:7 3:7
ìrètí ògo / Hope of Glory Col. 1:27
Ìrohin ayọ̀ idande/ Goodnews of redemption
àrólé ohun gbogbo / appointed heir of all things Heb. 1:9
ẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Ọlọrun / Fullness of the Godhead Col. 2:9
Ohun ògo / Excellent Isa 4:2
Ohun àmúyangàn / Comely One Isa. 4:2
Alàṣẹ áti onìdájọ́ / Executor of Judgment John 5:27
Kòríkòsùn Baba / Face of God John 1:18
Asoju Olóòótọ́ / Faithful Ambassador Proverbs 13:7
Ìmúpadàbọ̀sípò onigbagbo / Redeemer Job 19:25
Olorúkọ olókìkí títí lae / Everlasting name Isa 63:12
Ẹlẹ́rìí òtítọ́ / Faithful Witness Rev. 1:5
Alákòóso / General overseer Zech. 3:17
ìri ewe / Dew of youth Psalms 110:3
Ade ẹwà/ Diadem of Beauty Isa. 28:5
Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ onigbagbo / Help of believer
Mímọ́ mímọ́ mímọ́ / Holy holy holy
OLUWA mímọ́ / Holy and True Rev. 6:10
Ọlowọ́ agbara mimo / His Holy Arm Isaiah 52:10
Olorúkọ mímọ́ / Holy Name Psa. 33:21
Onidajọ́ mímọ́ / Righteous judge
Ẹnì ayérayé jókòó lórí itẹ̀ mímọ́ / A throne was set in heaven, and one sat on the throne.
Ojú wọ́n dàbí òkúta iyebíye / HE that sat was to look upon like a jasper and a sardine stone
Wọ́n wọ aṣọ ẹ̀wù funfun tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀ / Clothed with a garment down to the foot
Wọ́n fi ọ̀já wúrà gba àyà / with a golden girdle about his bust
Irun orí wọ́n funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú / HIS head and his hairs were white like wool, as white as snow
Ojú wọ́n ń kọ yànràn bí iná / HIS eyes were as a flame of fire
Ojú wọ́n mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan / HIS countenance was as the sun shines in his strength
Ẹsẹ̀ wọ́n dàbí idẹ tí ń dán / HIS feet like unto fine brass
Ohùn wọ́n dàbí híhó omi òkun / HIS voice as the sound of many waters.
Idà olójú meji tí ó mú n yọ jáde lẹ́nu wọ́n / Out of his mouth went a sharp twoedged sword
Ìtẹ́ OLORUN ń jó bí ahọ́n iná / HIS throne was like the fiery flame
Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, / There was a rainbow round about the throne, in sight like unto an emerald.
ìtẹ́ mẹrinlelogun yí ìtẹ́ OLORUN ká / Round about the throne were four and twenty seats
Àwọn Àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ / Upon the seats I saw four and twenty elders sitting,
Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ OLORUN / Out of the throne proceeded lightnings and thunderings and voices
Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin yí ìtẹ́ ká / In the midst of the throne, and round about the throne, were four beasts full of eyes before and behind.
Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun iranṣẹ / Thousand thousands ministered unto him,
ọ̀kẹ́ àìmọye sì dúró níwájú OLORUN / Ten thousand times ten thousand stood before him
Pelu duru ati ago wura / with the harp and their vials
Wọ́n nkọ mímọ́ mímọ́ mímọ́ / they sang holy holy holy
Mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ / I have questions for you, and I want you to answer me
Níbo lo wà, nígbà tí OLORUN OLODUMARE fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? / “Where were you when GOD laid the earth’s foundation?
“Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí / “Have you ever journeyed to the springs of the sea
Tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí? / Or walked in the recesses of the deep?
Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí / Have the gates of death been shown to you?
Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun?/ “Can you discover the depths of GOD?
Tabi kí o tọpinpin Olodumare? ” / Can you discover the limits of the Almighty?
“Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí OLORUN ń kó yìnyín pamọ́ sí rí / “Have you ever entered the storehouses of the snow
“Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò / Who cuts a channel for the torrents of rain?
Ati fún ààrá/ and a path for the thunderstorm,
Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì? / Does the rain have a father? Who is the father of dew?
Ìyá wo ló bí yìnyín / From whose womb comes the ice?
Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùu / Who gave the clouds their wisdom?
Ati ìmọ̀ sinu ìrì? / Or gave understanding to the dew?
Ṣé ẹ kò tíì mọ̀? / Have you not known?
Ṣé kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé / Haven’t you understood from the foundations of the earth?
OLORUN OLODUMARE ni ó jókòó lókè àyíká ayé / It is HE that sits upon the circle of the earth,
Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ, kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí OLODUMARE / GOD is great—HE is beyond our understanding! The number of his years is past finding out.
ỌBA to pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni won pase fun òjò wẹliwẹli, ati ọ̀wààrà òjò / HE says to the snow, ‘Fall on the earth; likewise to the small rain, and to the great rain of his strength.
ỌBA to pàṣẹ ti Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀, òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ / HE commanded the whirlwind to come out of its room and cold out of the north.
Eyin ara ipejopo Ore-ofe/People of Grace Assembly
Ìró ààrá ń kéde bíbọ̀ JESU KRISTI / HIS thunder announces the coming of JESUS CHRIST
Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún /Just as you do not know the path of the wind and how bones are formed in the womb of the pregnant woman
Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, / Indeed, if a man should live many years, let him rejoice in them all
ọjọ́ tí yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ / and let him remember the days of darkness, for they will be many.
Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀/ Let the one who does wrong, still do wrong
Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀/ and the one who is filthy, still be filthy
Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.”/ and let the one who is righteous, still practice righteousness; and the one who is holy, still keep himself holy.”
Iwe ifihan ori ikejilelogun ese ikokanla so wipe/ Revelations 22:11 says
“Mò ń bọ̀ ní kíá / Behold, I am coming quickly,
Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi / and My reward is with Me,
tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí / to render to every man according to what he has done.
Emura! Emura!! Emura!!!/ Be prepared
JESU ti fere de / JESUS is coming soon
H A L L E L U J A H ! ! !